Happy 47-year Birthday to Ooni of Ife, His Imperial Majesty Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi Ojaja ll.
Happy 47-year Birthday to Ooni of Ife, His Imperial Majesty Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi Ojaja ll.
Omo Ojaja fidi ote jale
Omo Ayi kiti Ogun
Omo etiri Ogun
Kare o Leyoo aje okun Ooni
Oke leyin Moore
O taye so bi igba
Omo Laade Omo Ibi ro Omo ajongbodo
Omo osun meru ti kun
Omo ibi ola ti n wa
Omo Ayikiti Ogun
tiri Ogun
Mo rejana bi oni roko aburo etiri
Omo Degbin
Mo nlo nre igbode Omo Luusi
Omo arugbo-ile igbode abika lorun
Omo o fose foso, komo Olominrin feeru fo
Omo oke mo ri tikun aya sile.
Omo afinju oloja mo ledena meji
Omo afinju oloja mo re pole owu.
wari oore naa ke e momo Olominrin,
Ona na ro mo Ooni ria.
Omo Ekun sun-un birade,
Omo Odelu kan- bi,
Omo opo mefa oo lerunwa
Ade temi efeefa ni ere
Omo bodere agboobon,
Ikoko degbo deru, .
Omo ajongbodo.
Omo Debooye
Omo Giesi ijana
Mo ba Giesi rejana
Mo ba Debooye a repole
Omo igun gbebo – mo re igbode
Omo igun la gba
Omo igun la je
Omo igun kogokogo lorule
Igun ile rin-in gbebo
Akalamagbo ile rin gbo eru titu
Bi ‘ha je tan mun tan
Han moke ikole gun
Mosi ikole Yanrin mi obu lode
ibi an ba ti ba’gun
a tii se igun loore
Omo igun aare mo re ipole
Omo igun gbebo igbode nile re
O re more bi oni roko
Ooro lo to rise de
Han magbala sawesu
Han merinla funfun sekeji Adimunia
Bilia oooo
Adimunia Orisa keji
Yesi a bimo re kope I’ooni o Adimunia.
Biila Egberin ekun
Ajalaye elegberin ikere
Egberin ekun naa si koni rise dodo Adimunia
Erin a fin bi okin
Omo erin gangan ile
Omo erin gangan ode
Omo erin fi mi joye korun mi mo
Omo erin fi mi joye ki ndekun bebe ona yiye
Abu ajana ogbe
Oba Adeyeye seerin oko bi idikun Oloja
Omo Ogunwusi Adefisan Yeuke
Koo ba ti mun’gun koloree
A ore a han
Omo Osun meru tikun
Omo oye ni moore
Maa niso ni gbangba
Omo Abodere
Omo Agboo ibon
Owolomu ero agbada
Omo Ayidina
Omo Ayilubii
Ponpola abeso jingbinni
O dabi oruru laofin
Oni rakun saye
Yesi b’ooni mi wi o
Oke an setile gun
Mo roke etiri
Ojaja mo mi rodi
Tigbo tiju a ke riri Ayidina
Odi ile lo mi ree ni
Abi toko – Ayilibii
Kegbo Keto Kaaabiesi ooo
Comments
Post a Comment